AKOLE ISE: ASA ATI OHUN ELO ISOMOLORUKO

Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba.

Gbogbo ohun ti olodumare da saye lo ni oruko. oniruuru ohun-elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo ni gba Ikomojade . Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko, I ba se omokurin tabi omobinrin tabi ibeji sugbon ni ibo miiran , ojo kesan-an ni won n so omokunrin lorunko, ojo keje ni ti obinrin ti awon ibeji ni ojo kejo.

 

Die lara ohun elo isomoloruko niyi,

Ohun eloIwure/adura
ObiBibi lobi n biku danu, bibi lobi n baarun danu, obi a bi ibi aye re danu.
OrogboOrogbo maa n gbo saye ni, o o gbo o, wa a to, wa a gbo kejekeje, o ko ni gbo igbo iya.
OyinA kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o o koni je ikoso laye.
OtiOti kii ti, oko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni t e
Epo pupaEpo ni iroju obe, aye re a roju.
IyoIyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu inu awon obi re dun.
AtaareAtaare kii bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun, oye re a kun fomo.
Aadunadun adun ni a n ba nile aadun, ibaje oni wole to o.
IrekeA kii ba kikan ninu ireke, ikoro ko ni wo aye re lae, aye re yoo dun
Omi tutuOmi la buwe, omi la bumu enikan kii ba omi sota,koo mu to

Ko ni gbodi ninu re o

Ko si ni sa pa o lori………

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ITAN AROSO – KIKA IW E TI IJOBA YAN

Igbelewon:

  • Kin ni asa isomoloruko?
  • Ko ohun elo isomoloruko marun un ki o si so bi a se n fi wure fun omo tuntun
  • Ko onka lati aadota de ogoorun

Ise asetilewa:Ise sise inu Yoruba Akayege for jssone

 

See also

AKOLE ISE: LITIRESO APILEKO

AKOLE ISE: LITIRESO APILEKO

AKOLE ISE: BI ASA SE JEYO NINU EDE YORUBA

ONKA YORUBA LATI OOKAN DE AADOTA (1-50)

AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *