Skip to content

Eyan ni awon wunren (oro) ti a fi n yan oro – oruko (noun) tai apola oruko (Noun phrase) ninu gbolohun tabi ninu isori. Bi apeere:

Iwe tuntun ni a f era

Aso ala ni mo wo

‘Tuntun’ ati ‘ala’ ti a fa ila si ninu gbolohun oke yii ni oro eyon ti o n se afikun itumo fun oro oruko ti won n yan.

Orisii eyan

  1. Eyan asapejuwe
  2. Eyan ajoruko
  • Eyan asafihan
  1. Eyan asonka
  2. Eyan alawe gbolohun asapejuwe
  3. EYAN ASAPEJUWE: Ise eyan yii ni lati pon oro oruko lona ti yoo fi ye ni tekeyeke. Oro apejuwe pin si ona meji, awon ni:
  4. Oro apejuwe ipile: iwonyi ni awon oro bii; pupa, rere, dudu, kekere, nla, funfun abbl.

Apeere lilo ni gbolohun

Nike je omo rere

Amala dudu ni mo feran

Ounje kekere ko le yo mi

 

  1. EYAN AJORUKO: Eyi ni oro oruko tabi oro aropo oruko ti a lo lati yan oro – oruko miiran. Bi apeere: Dokita oyinbo ni mo fe ri

Abule odu ni Busola n gbe

Ewure Torera ni ole ji

Ile wa ni a n lo

 

  1. EYAN ASOFIHAN: Eyi maa n toka si ohun ti a n soro nipa re. Weren tabi oro atoka re ni: wonyen, yii, yen, ati wonyi. Apeere:

Oro yen dun mo won ninu

Ile yii ga ju

Pasito gan-an ni mo fe ri

 

 

  1. EYAN ASONKA: Irufe eyan yii nii se pelu onka, o maa n toka si iye nkan ninu gbolohun. Bi apeere:

Omode meta n sere

Oko kan ni oluwa yan fun obinrin

Akara mefa ni mo je

Ile marun-un ni baba – agba ko

 

  1. EYAN ALAWE GBOLOHUN: ‘ti’ ni wunren atoka awe gbolohun asapejuwe. Ise re ni lati fi itunmo kun itumo oro – oruko ninu gbolohun. Bi apeere:

Gele ti a ran i ana wun mi

Ile ti mo ko ti kere ju

Baba ti o n soro re lo n bo yii

 

Ise Amutilewa

Toka orisii eyan ti o wa ninu gbolohun isale wonyii, ki o si fa ila si nidii.

  1. Oko wonyen ni mo fe ta
  2. Iyawo ti mo ni dara
  3. Eran dindin wu mi je
  4. Aso aran ni iya agba wo
  5. Oke meje ni a gbodo gunde ibe
  6. Iyana – Ipaja ti daru
  7. Oke nlanla wan i Efon Alaye

See also

AKORI EKO: ATUNYENWO LETA AIGBEFE (INFORMAL LETTER)

AKORI EKO: IHUN ORISIIRISII AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN

OSE KEFA ETO IGBEYAWO ABINIBI

ORISII ONA TI A N GBA SOGE NILE YORUBA

ETO ISELU ODE-ONI

2 thoughts on “AKORI EKO: EYAN”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *